Wo awakọ̀ tó yá ₦3.5m ní báǹkì láti fi polongo sáà kejì fún Tinubu, olóṣèlú méjì míràn l'Ekiti

Aworan awakọ naa lapa osi, sọwedowo miliọnu meji torukọ Aarẹ Tinubu wa wa lapa ọtun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lojuna ati ri i pe Aarẹ Bola Tinubu wọle fun saa keji ni 2027, awakọ akẹru kan, Adeleye Adeniyi, ti lọ ya miliọnu meji naira ni banki fun ipolongo ibo ati ṣiṣe atilẹyin fun un.

Yatọ si Aarẹ ti Adeniyi tori ẹ ya miliọnu meji naira, o tun ya miliọnu kan naira fun ipolongo ibo nitori Aṣofin Ekiti; Opeyemi Bamidele.

Bakan naa lo si ya idaji miliọnu naira nitori Steve Fatoba, ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti to loun fẹ ko ṣi maa wa nile igbimọ naa lọ.

Ile ifowopamọ Wema lo ti yawo naa, o fi sọwedowo mẹtẹẹta han awọn akọroyin to ṣalaye ara rẹ fun ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan lọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹwaa ọdun 2026.

Apapọ owo ti awakọ naa ya jẹ N3.5m.

"Mo mọ pe a maa ri nnkan daadaa gba si i lọwọ Tinubu bi a ba dibo fun un lẹẹkeji"

Sọwedowe to fi ya miliọnu meji naira lorukọ Aarẹ Bola Tinubu.

Adeleye Adeniyi, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si "Online Loan Man for BAO", ṣalaye pe:

"Mo n ṣe atilẹyin fun Aarẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lati pada wa fun saa keji. Mo ti yawo, mo fẹ fowo naa ṣe atilẹyin fun un nitori iṣẹ nla lo n ṣe.

"Mo ti ṣetan lati jade ki n si polongo ibo fun un. Orin ti mo si maa kọ lati ti i lẹyin ni "On your mandate we shall stand."

Sọwedowo to fi ya miliọnu kan naira lorukọ Ṣenetọ Opeyemi Bamidele

Bẹẹ ni Adeniyi wi.

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati dibo fun Tinubu, Opeyemi Bamidele ati Steve Fatoba.

Adeniyi sọ pe oun gbagbọ pe Aarẹ Tinubu yoo ṣe bẹbẹ si I fun araalu bi wọn ba le dibo yan an lẹẹkeji.

"A si maa ri ọpọlọpọ nnkan si i ju eyi ta a ti ri gba lọwọ rẹ lọ bi a ba dibo fun un lẹẹkeji.

"Mo rọ awọn ọmọ Naijiria bii temi ki wọn dibo fun un lẹẹkan si i."

Adeleye Adeniyi pẹlu ọkọ akẹro rẹ to le aworan ipolongo ibo Aarẹ Tinubu si.

Lorii Senetọ Opeyemi Bamidele to tun tori ẹ jẹ gbese, awakọ akẹru yii sọ pe oun maa n wo awọn iṣẹ idagbasoke ti Sẹnetọ naa n ṣe, o si maa n wu oun lori lati ṣe atilẹyin fun un.

O ni oun ti gba lọkan oun pe aṣiwaju rere ni.

Loṣu Keji ọdun yii, Adeniyi wọnu iroyin, pẹlu bo ṣe yawo lọwọ banki Opay, to si fi ṣe ipolowo si ara ọkọ kan to fi polongo Opeyemi Bamidele fun saa keji .

Sọwedowo to fi ya idaji miliọnu naira lorukọ Steve Fatoba.

Ko ṣai fi han pe iṣẹ ti awọn oloṣelu toun tori wọn yawo yii n ṣe lo mu oun gbe igbesẹ naa.

Adeniyi ko gbagbe gomina ipinlẹ Ekiti, Biodun Oyebanji, o ni o ṣe bẹbẹ lẹka ẹkọ, ilera, ipese ina ọba, idagbasoke igberiko ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa lo ṣe gboriyin fun Aarẹ Tinubu lawọn ẹka yii, o ni o ti ṣiṣẹ to han kedere to si yẹ ko pada wa fun saa keji.