Èèyàn méje bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá fún fífi owó ṣe òdòdó ìfẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ilu ti ko si ofin ni ẹṣẹ ko si, bi ofin ba ti wa, afi ki ilu tẹle e.
Ko din ni eeyan meje ti ọwọ ọlọpaa ti ba bayii lori ẹsun pe wọn fi owo orilẹede Ghana ti i ṣe Cedi ṣe ododo ifẹ ti a mọ si "Money bouquet"
Yatọ si pe wọn fi owo naa ṣe ami ododo ifẹ, wọn ni wọn tun to o bii ẹ̀yẹ si ara akara oyinbo (Cake).
"Iwa to lodi sofin ni, o si tumọ si ṣiṣe owo niṣekuṣe"
Gẹgẹ bi banki ilẹ Ghana ṣe ṣalaye lori iṣẹlẹ naa, iwa to lodi sofin ni awọn eeyan naa wu, pẹlu bi wọn ṣe fi owo Cedi to jẹ ajọna ilẹ Ghana ṣe ododo ifẹ.
Banki naa ṣalaye pe olobo lo ta awọn lori awọn eeyan naa ti gbogbo wọn jẹ obinrin, pe wọn n ta awọn ododo olowo naa kaakiri olu ilu Ghana ti i ṣe Accra.
Loṣu Keje ni banki naa kede ikilọ lori iwa yii, wọn si fi ye araalu pe o lodi sofin.
Ikilọ naa sọ pe biba owo Cedi loju jẹ ni, nigba ti ẹnikẹni ba fi ṣe nnkan mi-in to yatọ si níná.
Lori awọn ti wọn mu yii, ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, wọn si ni gbogbo wọn ni yoo foju bale ẹjọ.
Wọn le ṣẹwọn, o si le di ohun ti wọn yoo sanwo itanran nla bi ijọba ṣe sọ.
Aṣa fifi owo ṣe aworan tabi ododo ifẹ yii ti wọpọ ni Ghana, bẹẹ ni awọn orilẹede Africa mi-in naa si ti n kọ iṣẹ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe laipẹ yii ni awọn orilẹede bii Kenya, Naijiria, South Africa ati Botswana kede ikilọ, pe o lodi sofin lati fi abuku kan owo awọn orilẹede naa lọna yowu, yatọ si nina ti owo wa fun, amọ aṣa naa ṣi n waye.



























