Ṣé Adunni Ade onítíátà bímọ fún ọkọ ọlọ́kọ ni, ló ṣe gbé oyún àtọmọ tó bí lọ́dún méjì sẹ́yìn pamọ́? Áláyé rèé

Adunni Adewale (Adunni Ade) pẹlu ọwọ ọmọ rẹ, Sal. Ọmọ naa sun sori ibusu, wọn si ya ọwọ rẹ mejeeji ninu aworan yii, pẹlu awọn ẹgba ọwọ to rẹwa ti wọn fi si i lọwọ

Oríṣun àwòrán, iamadunniade/Instagram

Àkọlé àwòrán, Adunni Adewale (Adunni Ade) pẹlu ọwọ ọmọ rẹ, Sal.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan lori ayelujara, nigba ti wọn ri ikede ọmọ bibi ti gbajumọ oṣere ilẹ wa nni, Adunni Adewale tawọn eeyan mọ si Adunni Ade, ṣe soju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku, ọjọ keje, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii.

Ọjọ Aiku naa ni ayajọ ọjọọbi Adunni Ade, o si lo eyi lati ki ara rẹ ku ayọ ọjọọbi.

Lẹyin naa lo ba tun ṣalaye pe oun bimọ obinrin kan lọdun meji sẹyin, oun ko wulẹ jẹ kaye mọ ni.

"Idi ti mo ṣe gbe oyun atọmọ mi pamọ fun ọdun meji"

Nigba to n ṣalaye idi rẹ to fi ṣe oyun ati ọmọ bibi ni bonkẹlẹ ti ko han sawọn eeyan, Adunni Ade sọ loju opo naa pe:

"Lonii ọjọ ibi mi, mo pada n kede ohun ti a ti fi pamọ fun ọdun meji o le.

"Eyi ki i ṣe irinajo to rọrun. O ba ogun abẹnu de, bẹẹ ni asiko to dan mi wo ni, ti mo si fi ro ara mi lagbara si i.

"Bawọn eeyan ṣe n ri apa kan mi, ohun to ju bẹẹ lọ lemi n gbe ninu rẹ, ohun to si kan emi nikan ni."

Adunni Ade tẹsiwaju ninu alaye rẹ, pe aijẹ kaye mọ nipa oyun atọmọbinrin toun bi ki i ṣe ti pe wọn ko gbọdọ mọ.

O ni bi ko ṣe pe gbogbo ohun to ba daa kọ ni eeyan n gbe si igboro aye.

"A pinnu lati fi pamọ, ki i ṣe nitori a gbọdọ gbe e pamọ fun ẹnikẹni, ṣugbọn nitori pe ko sohun ti a le fi alaafia we, bẹẹ si ni ki i ṣe gbogbo ohun to ba daa ni gbogbo oju gbọdọ ri.

"A fẹ gbadun ibukun wa ni."

Bẹẹ ni Adunni Ade tẹsiwaju.

"Ọkọ ọlọkọ kọ ni mo bimọ fun, oore temi de pẹlu alaafia ni"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi ọpọ eeyan yoo ṣe maa ro o pe ta lo fun oṣere yii loyun, ti wọn yoo si fẹ mọ baba ọmọ rẹ, Adunni naa ti gbaradi fun iru eyi, lo ṣe tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe:

"Ki i ṣe gbogbo ìyá naa ni ohun ti ẹ ba n ro nipa wọn ri bẹẹ, ko si ki n ṣe gbogbo ọrọ naa lo n ba awuyewuye wa. Gbogbo oore to ba de kọ lo n mu ariwo dani.

"Ọlọrun fun mi ni temi ni kikun ni, pẹlu alaafia, o mọ-ọn-mọ fun mi ni. Ki i ṣe ọkọ ọlọkọ ni mo bimọ fun. Irin ajo wa ti fẹrẹ pe ọdun mẹwaa."

Oṣere ti iya rẹ jẹ oyinbo alawọ funfun naa fi kun un pe Oluwa lo fun oun atọkọ oun lọmọ akọkọ ninu irin ajo ifẹ, ọmo naa si jẹ obinrin.

O ni ọmọ naa jẹ apẹẹrẹ gbigba adura foun ati ololufẹ oun, ati ẹri pe Oluwa ṣi n da àrà lasiko to ba wu u.

O fi kun un pe awọn eeyan le maa foju kan wo Adunni Ade to wa lori ayelujara, ọtọ gedengbe ni Adunni Adewale nilee rẹ, o si ṣee ṣe ki ọrọ oun ma ye awọn kan, amọ ko buru.

Adunni Ade dupẹ lọwọ awọn eeyan to ti fi ifẹ otitọ han si i, bẹẹ lo gba a ladura pe ire tiwon naa yoo tọ wọn wa.

Bay Sal lo ni oun n pe ọmọbinrin to bi naa, to ti n le lọdun meji lọ bayii.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ta a ni Adunni Ade?

Adunni Adewale (Adunni Ade)

Oríṣun àwòrán, iamadunniade/Instagram

Adunni Adewale, ti ọpọ eeyan mọ si Aduuni Ade ni wọn bi silu New York lorilẹede Amẹrika.

Ọmọ bibi Ireland ni iya rẹ nigba ti baba rẹ jẹ alawọ dudu lati ilẹ Yoruba.

Ọmọ ọdun meji lo ti pada wa si Naijiria pẹlu awọn obi rẹ lati wa se ayẹye oku baba baba rẹ, ilu Eko si lo gbe dagba to fi di ọmọge.

Amọ o tun pada sorilẹede Amẹrika lati lọ sile ẹkọ fasiti nibẹ.

Gbajumọ osere tiata ni Adunni Ade lẹka ede oyinbo ati Yoruba lorilẹede Naijiria, o si tun maa n sisẹ asaraloge pẹlu.

O ti bimọ meji tẹlẹ, ko too bi Baby Sal to ṣikẹta.