"Ìdájọ́ ikú tí wọ́n dá fún àwọn tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì Owo kò dá ọmọ mi àti àbúrò mi méjì tí wọ́n pa padà"

Àkọlé fídíò, Idajọ ikọlu ṣọọṣi ọwọ
"Ìdájọ́ ikú tí wọ́n dá fún àwọn tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì Owo kò dá ọmọ mi àti àbúrò mi méjì tí wọ́n pa padà"
Published

Awọn eeyan ti wọn padanu eeyan niluu Owo lasikọ ikọlu ile ijọsin St. Francis lọdun 2022 ti sọ pe lootọ inu awọn dun si idajọ ti awọn to ṣiṣẹ ibi naa gba amọ idajọ ọhun do mọlẹbi wọn ti wọn padanu pada.

Ọkan lara awọn eeyan naa, Iyaafin Aderonke sọ pe gbogbo igba ni oyun maa n bajẹ mọ oun lara lẹyin iṣẹlẹ naa nitori oun maa n ronu.

O ni ẹgbọn oun ti wọn pa lasiko ikọlu ọhun bi ọmọ marun un silẹ, akata oun si lawọn ọmọ naa wa bayii.

Arabinrin naa fi kun pe egbo to ti jina ni iṣẹlẹ naa jẹ ti oun ba ti n ranti rẹ.

Aderonke ni aburo oun meji ati ọmọ oun kan lo ba ikọlu ṣọọṣi naa lọ

Ẹlomiran, arabinrin Margret Folayemi Attah to padanu ẹsẹ rẹ mejeji ati oju kan ninu iṣẹlẹ naa sọ lati ọdun mẹrin ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, igbesi aye oun ti yipada.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ alaye wọn pẹlu BBC Yoruba.