Wo ọ̀nà àrékérekè tuntun táwọn agbésùnmọ̀mí ń gbà r'owó ní Naijiria bàyìí yàtọ̀ sí gbígba owó ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Fun igba pipẹ wa, bi awọn agbesunmọmi tabi ajinigbe ba kọlu ibi kan, wọn yoo beere obitibiti owo lọwọ awọn ti wọn ji eeyan wọn gbe gẹgẹ bii owo itusilẹ.
Eyi ni ọna kan ṣoṣo ti ọpọ eeyan mọ ti wọn fi n ri owo ra nnkan ija atawọn ohun ti wọn n lo fi ṣiṣẹ laabi wọn.
Ṣugbọn lọwọ yii, ẹka kan to n ri si itọpinpin ibi towo n gba wọle, 'Nigeria Financial Intelligence Unit' (NFIU) ti sọ pe awọn agbebọn n fi ojoojumọ lekun si i nipa ọna ati maa rowo ṣiṣẹ laabi wọn ni.
Awọn ọna wo ni NFIU tọka si pe awọn agbebọn n lo wayi?
Irọ pipa ati ẹtan lori ayelujara:
Gẹgẹ bi NFIU ṣe wi, awọn eeyan kan wa nilẹ okeere ti wọn n lo ori ayelujara lati tọrọ owo fun awọn agbebọn pẹlu ẹtan.
Ẹka yii sọ pe awọn eeyan naa yoo purọ pe awọn n beere iranlọwọ owo lati fun awọn alaini ati lati ran eto ẹkọ lọwọ, gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch ṣe ro o.
Lilo atẹjiṣẹ:
Loju opo bii Telegram ati pinpin oju opo tawọn to fẹ ṣe itọrẹ aanu naa yoo fi owo ranṣẹ si, igba mi-in si ree, wọn yoo lo akanti banki gangan bi NFIU ṣe sọ.
"Ọpọlọpọ eeyan lo ti fi owo to to $50 to $500 tọrọ fun wọn, owo tawọn to n ṣe odiwọn owo ko ka kun.
*Wọn fi kun un pe ninu aṣunwọn kan to jẹ olori apo ikowosi ni wọn ti n gba owo ọhun, ilẹ okeere ni wọn ti n dari akanti naa, wọn yoo ṣẹṣẹ waa taari rẹ si ibomiran lẹyin ti wọn ba ti fẹnuko le iye ti wọn ba fẹ fi ranṣẹ.
*Lilo akanti ti wọn fi orukọ obinrin ṣi:
Ninu abajade mi-in ti ẹka iroyin Premium Times fi lede, wọn ni awọn to n ṣẹranlọwọ fun awọn agbebọn maa n lo akanti ti wọn fi orukọ obinrin ṣi lati fi gba owo.
Ẹka iroyin yii fi abọ iwadii NFIU gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, eyi to ni awon agbesunmọmi lọkunrin atawon to n ri si ohun eelo wọn maa n dọgbọn lo awọn akanti ti wọn fi orukọ iyawo atawọn aburo/ẹgbọn wọn obinrin ṣi.
Wọn fi kun un pe wọn n ṣe eyi nitori ijọba ki I saba fẹsun lilọwọ si iwa ọdaran nipasẹ owo kan awọn obinrin.
NFIU ṣalaye pe awọn ọkunrin to n lo akanti naa labẹlẹ ni yoo mu kaadi ATM rẹ dani ti wọn yoo si ma a lo o.
Ki ni wọn n fi owo naa ṣe bi wọn ba gba a tan?
NFIU sọ pe wọn maa n pin owo ti won b agba si isọri keekeekee, wọn yoo wa fi ranṣẹ lori ayelujara nipasẹ awọn ileeṣẹ to n ṣowo owó ilẹ okeere, atawọn oju opo ti eeyan le kowo si ni Naijiria.
Awọn mi-in ninu awọn ibi ti wọn n fi owo ọhun si jẹ akanti akẹkọọ, tawọn olokoowo kereje tabi tawọn ẹbi wọn.
Ẹka NFIU sọ pe wọn n ṣe eyi lati ma jẹ kawọn eeyan mọ ibi ti owo naa ti wa gan-an.
Bi owo naa ba balẹ tan si asunwọn tan, wọn yoo sọ ọ di kiṣi ti wọn le tẹwọ gba (cash) tabi ki wọn fi ra awọn nnkan eelo bii ọkada, ajilẹ atawọn itakun to le jẹ ki wọn maa jẹgbadun ẹrọ ayelujara lọ.
Wọn tun maa n lo lara owo naa fawọn to n ba wọn ṣiṣẹ, gẹgẹ bi NFIU ṣe sọ.
"Nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn n lo n ṣe idiwọ fun iwadii"

Oríṣun àwòrán, Gettz images
Ni itẹsiwaju alaye ẹka NFIU, wọn ṣalaye nipa bi nọmba ẹrọ ibanisọrọ tawọn agbesunmọmi n lo ṣe n ṣakoba fun iṣẹ iwadii.
Labẹ ilana ododo, awọn eeyan to ni akanti nile ifowopamọ maa n sabaa so nọmba wọn mọ akanti ti wọn ba ṣi ni, ki wọn le maa ri atẹjiṣẹ lorii foonu wọn, ki wọn si tun le ni anfaani si akanti naa, dipo ti yoo fi maa lọ sibi ti ko yẹ.
Ṣugbọn lọdọ awọn agbesunmọmi bi NFIU ṣe wi, orukọ awọn eeyan to ti ku tabi awọn ti wọn lo orukọ wọn lẹyin wọn ni won maa n fi silẹ, wọn n ṣe eyi lati ma le fi idanimọ ẹni to ni nọmba naa han.
"Wọn maa n dalẹ adehun aabo to yẹ ko wa laarin banki ati awọn nọmba ibanisọrọ, nipa lilo nọmba ti ko si akọsilẹ fun, abi awọn mi-in ti wọn fi orukọ awọn to ti ku silẹ, abi awọn mi-in ti wọn fi orukọ obinrin ṣi."
Abajade NFIU lori eyi ni pe o maa n di iwadii lọwọ, nitori bi oluwadii ba ti pade iru eyi, wọn maa n fi iwadii naa silẹ lai ṣe mọ ni, awọn oniṣẹ ibi naa yoo si maa ba iṣẹ wọn lọ.
NFIU fi ISWAP ṣe akawe ọrọ, ti wọn ni wọn n lo ohun ti ko fidi iṣẹ ti wọn n ṣe gan -an mulẹ.
Bakan naa ni wọn tun n lo awon nọmba ati ọrọ ti ẹnikẹni ko mọ fi ṣiṣẹ wọn.
Wọn maa n paarọ ede nigba mi-in tabi ki wọn lo ọrọ ti eeyan ko le foju si lara.


























