Ọ̀rọ̀ oyè Awùjalẹ̀ tún gbọ̀nà míràn yọ; agboolé Fusengbuwa wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun àtàwọn Afọbajẹ lọ sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, others
Awọn agboole ẹbi Fusengbuwa ti ipo ọba Awujale tilẹ Ijẹbu kan niluu Ijebu-Ode ni wọn ti wọ ijọba ipinlẹ Ogun ati awọn Afọbajẹ lọ siwaju ile-ẹjọ.
Ko si nnkan meji ti a gbọ pe o fa igbesẹ yii, bi ko ṣe bi ijọba ipinlẹ naa ṣe gbẹsẹ le gbogbo eto yiyan ọba tuntun fun Akilẹ Ijẹbu, lẹyin ipapoda Ọba Sikirulai Kayode Adetona lọdun to kọja.
Ile-ẹjọ giga to wa niluu Ijebu-Ode ni awọn mọlẹbi naa wọ ijọba ipinlẹ Ogun ati awọn Afọbajẹ lọ, ninu ẹsun ti nọmba rẹ jẹ HCJ/149/2026, nibi ti wọn ti n rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun igbimọ awọn Afọbajẹ lati bẹrẹ gbogbo eto yiyan Awujale tuntun pade lai fi akoko ṣofo.
Awọn mọlẹbi naa sọ pe awọn fẹ ki igbimọ Afọbajẹ bẹrẹ eto yiyan Awujalẹ tuntun pada, ki wọn si tete pari rẹ ni kiakia.
Bakan naa ni wọn tako bi awọn ọlọpaa ṣe ti Aafin Awujale pa, eyi ti wọn sọ pe ko ṣẹyin aṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun lati da gbogbo eto yiyan ọba tuntun duro.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025 ni Ọba Adetona tẹri-gbaṣọ, to si jẹ ki ipo Awujale tii ṣe olori ọba nilẹ Ijebu ṣofo.
Ṣugbọn lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2025 ni ijọba ibilẹ Ijebu-Ode fi iwe ranṣẹ si awọn olori ẹbi Fusengbuwa lati fi to wọn leti pe awọn ni ipo ọba kan, ni ibamu pẹlu ayipo ipo naa ati ni ibamu pẹlu ofin jijẹ oye ati ọba nipinlẹ Ogun, eyi ti wọn ṣagbekalẹ rẹ lọdun 2021.
Eyi lo fa a, ti awọn mọlẹbi naa fi bẹrẹ fifa ọmọ oye kalẹ fun ipo Awujale, iyẹn lọjọ kejila, oṣu Kinni, ọdun 2026.
Ọjọ mẹrinla gbako ni ipin kinni ninu abala kẹrindinlogun ninu iwe ofin naa fi silẹ lati fi pari gbogbo eto fifa ọmọ oye kalẹ.
Ọmọọba ati Ọmọọbabinrin ti ko din ni marundinlọgọrun-un ni wọn jade sita lati du ipo kan ṣoṣo ọhun, koda ti awọn olori ẹbi ọhun fi gbogbo orukọ ati iwew-ẹri wọn ranṣẹ sawọn Afọbajẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kinni, ọdun yii.
Ṣugbọn ṣadeede ni awọn olori ẹbi naa sọ pe awọn ọlọpaa yabo Aafin Awujalẹ, ti wọn ko si jẹ ki awọn Afọbajẹ wọle lati tẹsiwaju eto yiyan ọmọ oye kan ṣoṣo.
Lẹyin naa ni awọn alakoso ijọba ibilẹ Ijebu-Ode gbe igbesẹ lati da gbogbo eto yiyan ọba Awujale tuntun duro, pẹlu oniruuru ẹsun to nii ṣe pẹlu iwa magomago ati gbigba abẹtẹlẹ.
Kí ló wà nínú ìwé ẹ̀sùn wọn?
Ninu iwe ẹsun ti awọn mọlẹbi naa gbe lọ siwaju ile-ẹjọ, wọn ni awọn ti tako ẹsun iwa magomago ati gbigba abẹtẹlẹ, nitori pe ko si iwe to ti ẹsun naa lẹyin, bi ko ṣe pe ọrọ ẹnu lasan ni.
Wọn jẹ ko di mimọ pe iwadii awọn ọlọpaa ati ileeṣẹ ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ ko fidi aṣemaṣe mulẹ lẹyin abajade iwadii wọn.
Iwe ẹsun naa tun darukọ alaga ijọba ibilẹ Ijebu-Ode, Ọnarebu Dare Alebiosu, ẹni to paṣẹ pe ki eto yiyan ọmọ oye bẹrẹ; ati kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ ati Oye jijẹ, Ọnarebu Ganiyu Hamzat
Awọn olori ẹbi naa fẹsun kan Hamzat wi pe oun lo kọwe ẹsun ranṣẹ si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun lati pe gbogbo awọn Afọbajẹ ati awọn alẹnulọrọ lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.
Wọn n rọ ile-ẹjọ lati gbe aṣẹ kalẹ wi pe abajade gbogbo eti awọn olori ẹbi naa fidi mulẹ, ati pe awọn Afọbajẹ, ni ibamu pẹlu abala kẹrindinlogun iwe ofin oye jijẹ, yan ọmọ oye kan ṣoṣo, ki wọn si fi orukọ rẹ ranṣẹ si igbimọ iṣakoso ipinlẹ Ogun.
Ìyẹn nìkan kọ́
Wọn lawọn fẹ aṣẹ pe ijọba ipinlẹ naa ko ni aṣẹ kankan labẹ ofin lati da eto yiyan ọmọ oye fun ipo ọba duro, ati pe ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ki awọn Afọbajẹ bẹrẹ igbimọ wọn pada lẹyin ọjọ meje idajọ naa lati pari gbogbo eto yiyan ọmọ oye fun ipo ọba.
Bakan naa ni wọn tun n fẹ iwe aṣẹ idanilọwọkọ lati ma jẹ ki ijọba ipinlẹ naa, pẹlu awọn eleto aabo da si gbogbo ilana wọn.
Igbimọ agbẹjọro mọlẹbi ọhun ti Ọtunba Olusegun Otayemi lewaju rẹ sọ pe iwe ofin oye jijẹ nipinlẹ naa ṣagbekalẹ ilana lati ori gbigba fọọmu, yiyan ọmọ oye, ati bibu ọwọ lu ọmọ oye, eyi ti wọn sọ pe, wọn gbọdọ tẹle.
Wọn wa fi idajọ ti Menakaya v. Menakaya ati Garba v. University of Maiduguri to waye laipẹ ṣe aritọkasi ninu ẹbẹ wọn, wi pe ki idajọ ododo le waye.
Yatọ si ijọba ipinlẹ Ogun, wọn tun darukọ Gomina Dapo Abiodun, Adajọ agba ipinlẹ naa, to fi mọ igbimọ iṣakoso ati awọn alẹnulọrọ ninu ẹjọ naa.


























