'Fóònù àti tẹlifíṣàn àwòjù le è ṣe àkóbá fún ọpọlọ ọmọ rẹ'

'Fóònù àti tẹlifíṣàn àwòjù le è ṣe àkóbá fún ọpọlọ ọmọ rẹ'
Published

Njẹ o mọ pe awoju mohunmaworan ati ẹrọ ibanisọrọ le e fa ọpọ akude ba ọmọ rẹ?

Bẹẹni! Iwadi ijinlẹ kan fi idi rẹ mulẹ wi pe bi awọn ọmọde ma n ran oju mọ oju tẹlifiṣan tabi foonu ju, o lee maa fa ikayasoke ati awọn ohun miran fun wọn.

Iwadi naa ni o dara ki awọn obi tabi alagbatọ o maa fi gbendeke le iye akoko ti awọn ọmọ wọn le lo pẹlu awọn ohun mejeeji yii.

Iwadii naa ni eyi ṣe pataki bibẹẹkọ o lewu fun idagbasoke ọpọlọ ọmọ rẹ.

Iṣẹ iwadii naa ti ajọ Amẹrican Institutue of Paediatrics ṣe sọ pe iye akoko ti awọn ọmọ n lo pẹlu mohunmaworan ati ẹrọ ibanisọrọ niiṣe pẹlu idagbasoke ọpọlọ wọn.