You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ajínigbé tó kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìnbọn sí wa nígbà tí a ń lé wọn wọgbó ìbọn wà kò ràn wọ́n ni – Àwọn ọlọ́dẹ ìlú Esinele
Lọjọ Ẹti to kọja ni awọn agbebọ̀n kọlu awọn ileẹkọ meji kan ni ilu Esinẹlẹ ati Yawọta ni ijọba ibilẹ Oriire ni ipinlẹ Ọyọ.
BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu naa lati mọ bi awọn nnkan ṣe n lọ si nibẹ lẹyin iṣẹlẹ naa.
Iwọnba perete awọn eeyan to wa ni ilu naa kun fun ibẹrubojo bi o tilẹ jẹ wi pe wọn ni ifarahan awọn ẹṣọ alaabo atawọn ologun ti gunlẹ si ilu naa fi awọn lọkan balẹ. Awọn ologun na wa nibẹ lati rii daju pe abo to peye wa nibẹ, ki wọn si le wa ọna lati ri awọn ti wọn ji gbe gba pada.
Kabiyesi ilu naa ṣalaye fun BBC News Yoruba ipade lọna ati wa idaabo bo ilu awọn ni wọn n ṣe lọw nigba ti awọn agbebọn naa wọnu ilu.