Ọba Adeyemi Adediran, Owamiran ti ìlú Esa-oke wàjà

Oríṣun àwòrán, Esa Oke City Praise
Gomina Ademola Adeleke ti ba awọn ẹbi, iluu Esa-oke ati gbogbo ọmọ Ijeṣa lapapọ kẹdun ipapoda Ọba Adeyemi Adediran to waja.
Ninu atẹjade ti Rasheed Olawale, ẹni to jẹ agbẹnusọ fun gomina Ademola Adeleke lede lo ti fidi rẹ mulẹ pe Ọba Adeyemi Adediran, Owamiran ti iluu Esa-oke ti waja.
Ana ni a gbọ pe, igbakeji si ọba Adeyemi Adediran ti iluu Esa-oke, Ogboni ti iluu Esa-oke, Oloye Paul Olamiju kede konilekogbele fun wakati mẹrinlelogun lati fi ṣe awọn etutu pataki fun Ọba Adeyemi Adediran to wa ni ori aarẹ.
Ṣugbọn ikede konilekogbele naa lo mu ipaya ba awọn olugbe iluu Esa-oke latari bi wọn ṣe mọ pe, Ọba Adeyemi n ṣe aarẹ bii ọsẹ diẹ sẹyin.
Ninu atẹjade ti Rasheed Olawale fi lede lo ti sọ bi ipapoda Ọba Adeyemi ṣe dun gomina Ademola Adeleke to.
Oni, gomina Ademola Adeleke ṣe apejuwe Ọba Adeyemi gẹgẹ bii ẹni to fẹran iluu rẹ ati ẹni to ko eeyan mọra to si jẹ ẹni to tun fẹran alaafia gidigidi.
Gomina Adeleke, tun tẹsiwaju pe oun ba ẹbi, ara, ati gbogbo ọmọ bibi iluu Esa-oke ati paapaa julọ gbogbo ọmọ Ijeṣa kẹdun ipapoda Ọba naa.
Gomina Ademola Adeleke ki wọn pe ku ara fẹẹ ra ku ti ọba ọhun.
Gẹgẹ bi oun ti o wa ni akọsilẹ. Ọba Adeyemi Adediran, gori itẹ awọn baba-nla rẹ ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ọdun 2004, to si papoda ni ọjọ kẹfa, osu Karùn-ún, ọdun 2026.
Ọba Adeyemi Adediran lo ọdun mejilelogun lori itẹ ki ọlọjọ to de.




























