Ọkọ̀ tó kó àwọn agbábọ́ọ̀lù pàdé àwọn adigunjalè lọ́nà, wọ́n yìnbọn pa agbábọ́ọ̀lù kan

Oloogbe Dominic Frimpong, agbabọọlu ilẹ Ghana ti adigunjale yinbọn pa

Oríṣun àwòrán, Aduana FC/X

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Dominic Frimpong
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Agbabọọlu kan, ọmọ orilẹede Ghana, Dominic Frimpong, ti di oloogbe bayii, lẹyin ti ikọ adigunjale kan yinbọn mọ ọkọ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ lasiko ti wọn n bọ lati ibi idije ere bọọlu.

Ikọ agbabọọlu Berkum Chelsea ti Dominic wa lo ko awọn adigunjale lọna lọjọ Aiku ọsẹ yii.

"Awọn ọkunrin ti wọn fi àwọ̀n bo oju, ti wọn n ṣafihan ibọn lo dena de wọn, wọn gbegidina bi awọn ikọ agbabọọlu naa ṣe n pada silẹ lọjọ Aiku."

Ẹgbẹ agbabọọlu naa lo ṣalaye bẹẹ.

Ibọn ti awọn ole naa yin lo ba Dominic bi wọn ṣe sọ.

Bakana naa ni awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe ibọn ba Oloogbe Frimpong, o si ku lasiko to n gba itọju lọwọ.

Iwadii ti bẹrẹ lati mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa mu.

Ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Ghana, Ghana Football Association (GFA), fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ yii.

Wọn ṣapejuwe Oloogbe Dominic bii ẹni to fi gbogbo ara jin fun ikọ rẹ.

Bawo ni iṣẹlẹ naa se waye?

Ikọ agbabọọlu naa n bọ lalẹ lati ibi idije Ghana Premier League ti wọn gba tako Samartex, ni Samreboi, eyi to jẹ kilomita - 270km si Berekum.

Wọn tilẹ padanu idije naa pẹlu ami ayo kan si odo.

"Awọn ọkunrin naa bẹrẹ si I yinbọn si ọkọ bọọsi to gbe wa, bi dẹrẹba ṣe n gbiyanju lati dari ọkọ pada.

"Awọn agbabọọlu atawọn oṣiṣẹ sa wọgbo lati sa asala fun ẹmi wọn."

Atẹjade ti ikọ Berekum Chelsea fi sita lọjọ Aje ni wọn ti ṣalaye bẹẹ.

Ṣugbọn Dominic fi ara gba ọta bi atẹjade naa ṣe ṣalaye.

Agbabọọlu ọgbọn (30), ni awọn alaṣẹ Ghana sọ pe ọkọ naa ko, pẹlu awọn oṣiṣẹ mi-in.

Wọn ni ori irin naa ni wọn wa ti wọn fi ko awọn adigunjale mẹfa to dihamọra ogun lọna.

Bawọn ẹlẹgiri naa ṣe ṣina ibọn bole lo ba Dominic, to si pada dagbere faye.

Ta a ni Dominic Frimpong?

Ẹni ogun ọdun ni Oloogbe Dominic Frimpong, ọmọ orilẹede Ghana ni.

Oṣu Kin-in-ọdun yii lo darapọ mọ Berekum Chelsea nilana pe wọn n ya a lo ( Loan) lati ẹgbẹ agbabọọlu Aduana.

Eto to wa nilẹ ni pe Frimpomg to n gba ọwọ iwaju, yoo wa pẹlu wọn titi di opin saa igbabọọlu premier league.

O ti gba bọọlu sawọn nigba meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtala to ti kopa ki iku ojiji too pa oju rẹ de bayii.

Ẹgbẹ agbabọọlu Berekum Chelsea ti Oloogbe wa yii ni a mọ si Semereka FC tẹlẹ, nigba ti wọn da ẹgbẹ naa silẹ ni 2000.

Ọdun mẹrin lẹyin eyi ni wọn yi orukọ pada, lẹyin ti wọn gbe Michael Essien, gbajugbaja ọmọ ilẹ Ghana ninu ẹgbẹ naa lọ si ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea.

Eyi fun ikọ naa lokiki pupọ ni Ghana, wọn si fi Chelsea kun orukọ wọn.

Araalu koro oju si iṣẹlẹ yii

Iṣẹlẹ yii ti mu ki ọpọ eeyan koro oju si aabo ti ko peye lawọn oju ọna ilẹ Ghana.

Eyi to pa Dominic yii kọ ni akọkọ, awọn ikọ agbabọọlu bii FC Savannah, Wa All Stars, Legon Cities ati Ashanti Gold ni iroyin sọ pe wọn ti koju ikọlu bi eyi ri.

Akọroyin ere idaraya kan ni Ghana, Muftawu Abdulai, ṣapejuwe ohun to n ṣẹlẹ ni Ghana bayii bii iyalẹnu ati ijakulẹ.

"Bi ẹmi awọn eeyan abi ti awọn to da idije silẹ ko ba ri aabo, a jẹ pe ko si idi kan lati maa ba ere naa lọ mọ niyẹn."

Abdulai lo sọ bẹẹ fun BBC Sport Africa.

Ṣaa, ajọ GFA to n ri si bọọlu afẹsẹgba ni Ghana ti sọ pe oun yoo ṣe agbeyẹwo bi nnkan ṣe n lọ, oun yoo si so okun aabo le si I fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ba n rin irinajo fun idije laaarin ilu Ghana, lati dena iru iṣẹlẹ aburu yii lọjọ iwaju.