Ẹbí ọlọ́kadà tó kú n'Ibadan lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá dá a dúró ké gbàjarè, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàlàyé nǹkan tó ṣẹlẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹbi ọlọkada to ku lẹyin tawọn ọlọpaa da a duro lagbegbe Moniya niluu Ibadan ti ke gbajare lori iṣẹlẹ naa.

Ambali Salisu to jẹ ẹgbọn Sanni Salisu ọlọkada to doloogbe lagbegbe Moniya niluu Ibadan sọ fun BBC Yoruba wi pe ọlọpaa lo fi igi gba aburo oun ni aya, ti o si ṣubu lati ibẹ.

Ambali sọ pe igba toun n lọ si Kara lagbegbe Eleyele loun ri bawọn eeyan ṣe pọ nile iwosan kan, eyi to jẹ koun beere wi pe ki lo ṣẹlẹ nibẹ.

O ni oun ko tiẹ mọ pe aburo oun gan an ni nnkan ti ṣẹlẹ si.

Ambali ṣalaye wi pe nigba toun sọkalẹ loun ri pe aburo oun lẹni naa tawọn eeyan tori rẹ pejọ.

O ni ọlọpaa kan to n ṣiṣẹ ni Kara ti orukọ rẹ n jẹ Ibrahim lo ṣekupa Sanni.

''Ohun ti mo gbọ ni pe ọlọpaa naa beere owo lọwọ Sanni, o si fun lowo naa.

Amọ, ọlọpaa ọhun ni owo to foun kere, bayii ni Sanni da a lohun pe oun kii ṣe ọlọkada; ati pe oun n ko ẹru oun lọ sọja ni.

Bayii ni ọlọpaa naa sọ pe oun ko ni gba, o si yọ kọkọrọ lẹnu ọkada rẹ.

Aburo mi n bẹ ọlọpaa naa, ko si kuro lori ọkada rẹ.

Lẹyin naa ni ọlọpaa yii fi igi gba Sanni laya, bayii ni ọmọ naa ṣubu ti o si fi ankọọbu si i lọwọ.

Nigba ti o ri bi ọmọ naa ṣe n ke irora lo gbe e lọ sile iwosan, amọ, eleeru ti sungi ki o to gbe e de ile iwosan.

A wa sọ fun ọlọpaa naa wi pe a o ni gba oku Sanni lọwọ rẹ, bayii lo ṣe gbe oku rẹ kalẹ ti o si salọ,'' Ambali ṣalaye.

''Ko si ẹni to ran awọn ọlọpaa niṣẹ ti wọn lọ ṣe loju popo''

Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọlọpaa ko fi igi lu ọlọkada naa rara.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olayinka Ayanlade, ni iwadii ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ti fi han pe ọlọpaa ko fi ọwọ kan ọlọkada naa.

Alayande sọ pe ''idaduro ati ayẹwo tawọn ọlọpaa meji naa n ṣe lopopona Moniya lọjọ naa ni Ibadan kii ṣe eleyii ti ileeṣẹ ọlọpaa fọwọ si.

Ko si ẹni to ran awọn mejeeji ni iṣẹ ti wọn lọ ṣe loju popo.

Ekeji ni pe wọn da ọlọkada kan ti a mo orukọ rẹ si Salisu duro.

Bayii ni awọn ọlọpaa meji yii bẹrẹ sii sọrọ pẹlu Salisu, ṣadeede ni ọlọkada naa ṣubu to si bẹrẹ sii pofolo.

Lẹyin naa ni wọn gbe e lọ sile iwosan nibi tawọn dokita ti sọ pe o ti ku.''

Ayanlade ni awọn ọlọpaa ti wọn da ọlọkada naa duro ti wa ni atimọle bayii.

O ni iwadii si ti bẹrẹ lori nnkan to ṣẹlẹ laarin wọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori yoo foju wina ofin.

Ọgbeni Ayanlade ko ṣai bẹnu ẹtẹ lu bi awọn eeyan kan ṣe danu sun ọpọ dukia olowo iyebiye ni agọ ọlọpaa to wa ni Moniya lori iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, ẹgbọn oloogbe naa ti sọ pe awọn ti sin oku Sanni tori awọn ti gba fun Ọlọrun lori iku rẹ.

O ni awọn o ṣẹjọ, ṣugbọn oun yoo rọ ijọba lati ṣeranwọ fun ẹbi rẹ tori iyawo meji lo ni, o si bimọ mẹrin.

Amabali fikun ọrọ rẹ pe ọkan lara awọn iyawo Sanni si wa ninu oyun pẹlu.