Bàbá mi ló pàṣẹ fún mi lójú àlá pé kí n máa múra bí ọkùnrin – Funmilayo Elemure Ogunyemi

Àkọlé fídíò, Bàbá mi ló pàṣẹ fún mi lójú àlá pé kí n máa múra bí ọkùnrin – Funmilayo Elemure Ogunyemi
Bàbá mi ló pàṣẹ fún mi lójú àlá pé kí n máa múra bí ọkùnrin – Funmilayo Elemure Ogunyemi
Published

Ọmọ gbajumọ akọrin ibilẹ Ekiti, Elemure Ogunyẹmi, iyẹn Arabinrin Funmilayọ Elemure Ogunyẹmi ti kede pe Baba oun lo ni ki oun maa mura bi ọkunrin jade, paapaa lasiko ti oun ba n lọ sode ere.

Arabinrin Funmilayọ ṣalaye pe lootọ eyi ko dun mọ awọn akẹgbẹ oun lọkunrin ti wọn n kọ irufẹ orin yii kan naa.

Ninu ifọrọwerọ yii to ṣe pẹlu BBC News Yoruba, gbajumọ akọrin ibilẹEkiti naa ṣalaye pe oju ala ni baba oun ti yọ si oun lẹyin iku rẹ, to si ti paṣẹ fun oun lati maa mura bi ọkunrin.

O ni nigba kan ri oun ti kọ orin Fuji ki awọn eeyan to pe oun joko pe bi igba ti oun n ṣe iṣẹ oniṣẹ ni, ati pe yoo dara ki oun lọ tọ ipasẹ iṣẹ orin ibilẹ Ekiti ti baba oun, Elemure Ogunyẹmi maa n kọ.