Amẹ́ríkà gbégi dínà Strait of Hormuz láti dí Iran lọ́wọ́ gbígbé epo gba ibẹ̀, China figbe ta pé ewu ń bẹ̀, bí owó epo ṣe wọ́n sí ní àgbáyé

Ọkọ oju omi to n ko epo rọbi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Owo epo rọbi tun ti goke si lagbaye ni nnkan bii ida meje fun agba epo kan lẹyin ti Aarẹ Donald Trump kede pe ki awọn ọmọ ogun oun di oju ọna ti Iran n ko epo gba lẹyin ti ijiroro jogun-o-mi laarin Washington ato Tehran fori ṣanpọn.

Ni bayii, owo epo naa tun ti le ni $100 lẹyin ikede Aarẹ Trump ọhun.

'Brent crude' to maa n sọ nipa iye ti owo epo jẹ lagbaye ti di $102.02 fun agba epo kan ko to tun pada ja si $98 lọjọ Aje.

Lọjọru to kọja, owo epo naa ja silẹ si $100 lẹyin ti Washington ati Tehran fẹnuko lati gbe ogun wọn ti fun ọsẹ meji, amọ o tun ti pada goke si bayii.

Ileeṣẹ ọmọ ogun Iran ti sọ pe o lodi si ofin bi Amẹrika ṣe fẹ bẹgidina Strait of Hormuz

Wayi o, ijiroro to fori ṣanpọn yii ti mu ki ọpọ kọminu lagbaye pe o ṣeeṣe ki iṣoro ọrọ epo rọbi tubọ gogo si.

Oju ọna ori omi ti ida ogun ninu ọgọrun (20%) epo rọbi maa gba kọja lagbaye lo ti di oju ọna ewu bayii lẹyin ti Iran dunkoko pe oun yoo maa ju ado oloro si eyikeyi ọkọ to ba gba ibẹ kọja lẹyin ikọlu Amẹrika.

Amọ ṣa, Iran n ko epo jade loorekoore.

Windward, to maa n woye bi epo ṣe n kọja lagbaye sọ pe, miliọnu mejidinlọgọta agba epo ni Iran ti ko jade lati erekusu Kharg lọ si China lati ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2026.

Ọjọ Isinmi to kọja yii ni Aarẹ Trum kede pe awọn ọmọ ogun oun yoo bẹrẹ si n gbegi dina oju ọna Strait of Hormuz, ki awọn ọkọ to n ko epo kọja ma le ri aye lati kọja mọ.

Amọ ileeṣẹ ọmọ ogun Iran ti sọ pe o lodi si ofin bi Amẹrika ṣe fẹ bẹgidina Strait of Hormuz ọhun.

Bakan naa, orilẹede China to n jẹ anfaani epo rọbi lati ilẹ Iran loore koore ti wa kede pe ewu n bẹ bi ilẹ Amẹrika se gbegi dina oju ọna Strait of Hormuz naa lati mase jẹ ki epo Iran sita.

Iran daba wiwọgile ipese Uranium fun ọdun marun un lati fopin si ogun to lọ lọwọ

Ẹwẹ, ijọba Iran ti daba wiwọgile pipese ohun elo uranium fun ọdun marun un lati fopin si ogun to lọ lọwọ naa.

Amọ ijọba Amẹrika kọ jalẹ pe oun ko ni gba ayafi ti wọn ba gba lati dawọ rẹ duro fun ogun ọdun o kere tan.

A gbọ pe lara ijiroro orilẹede mejeji to waye ni Pakistan ni pe ki Iran fopin si ṣiṣe ohun elo ohun ija oloro nuclear amọ ijiroro naa tun lulẹ.

Amọ ṣa, o si ṣeeṣe ki wọn ni ijiroro ojukoju mii lọna ati gba alaafia laaye laipẹ.

Ileesẹ iroyin BBC kan si ọọfisi ijọba Amẹrika, White House lori ọrọ naa.

Lara ohun to fa ogun to n lọ lọwọ ni ohun elo agbara nuclear ti Iran ni.

Ijọba Amẹrika ti sọ ni gbangba pe oun ko ni gba ki orilẹede Iran ni ohun elo tabi ṣe ohun ija oloro nuclear kankan nitori awọn alakatakiti rẹ le kogun ja oun lọjọ iwaju.

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ní kò sí ayé, ayé wà o, ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí wà nínú iṣẹ́ tíátà - Tosin Olaniyan

Ìjíròrò láàárín Amẹ́ríkà àti Iran láti fòpin sí ogun forí sánpọ́n

Igbákejì Ààrẹ Amẹ́ríkà, JD Vance wà ní apá òsì, gbohùn wà níwájú rẹ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ okèèrè Iran, Esmaeil Baqaei wà ní apá ọ̀tún, ó ń wo ẹ̀gbẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Reuters

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Iran ti kọ̀ láti fẹnukò láti fòpin sí ogun lẹ́yìn tí àwọn méjéèjì kọ̀ láti fẹnukò lórí àwọn ìbéèrè wọn.

Ní ọjọ́rú ni orílẹ̀ èdè méjéèjì fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n fi jíròrò lórí àwọn nǹkan tó ń fa ogun náà àti bí wọ́n ṣe le parí rẹ̀.

Ìlú Islamabad, olú ìlú orílẹ̀ èdè Pakistan ni wọ́n fẹnukò pé kí ìjíròrò náà ti wáyé lẹ́yìn ìgbésẹ̀ ààrẹ Pakistan àti ààrẹ China dá sí ìkọlù tó ń wáyé náà.

Àwọn nǹkan tí Amẹ́ríkà ń bèèrè kò tọ̀nà lábẹ́ òfin - Iran

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àmọ́ lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní iléeṣẹ́ ìròyìn Iran fi ìkéde síta pé Iran àti Amẹ́ríkà kò ríbi fẹnukò lórí ìgbésẹ̀ àlááfíà nítorí àwọn nǹkan tó lágbára tí Amẹ́ríkà ń bèèrè fún.

Wọ́n ní àwọn ti so ìjíròrò náà rọ̀ fún ìgbà kan ná nítorí gbogbo akitiyan àwọn láti jẹ́ kí ìjíròrò náà lọ déédéé kó sì so èso rere ló já sí pàbó látàrí àwọn nǹkan tí kò wúlò tí Amẹ́ríkà ń bèèrè fún.

Bákan náà ni agbẹnusọ iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè Iran, Esmaeil Baqaei nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìjíròrò náà sọ pé àṣeyọrí ìjíròrò náà wà lọ́wọ́ Amẹ́ríkà.

Ó ní òun kò lérò pé ẹnikẹ́ni máa gbàgbọ́ pé àwọn máa fẹnukò kíákíá àti pé ó ṣòrò kí àwọn fẹnukò lẹ́yìn ìpàdé kan ṣoṣo.

Baqaei sọ pé Amẹ́ríkà nílò láti dènà bíbéèrè fún àwọn ohun tó lágbára àtàwọn ohun tí kò bá òfin mu, kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àti ìfẹ́ Iran.

Lára àwọn ohun tó ní àwọn jíròrò lé lórí ni Strait of Hormuz, ètò ṣíṣe àdó olóró "nuclear weapon" àti fífi òpin sí gbígbé ogun ti Iran pátápátá.

Ó fẹ̀sùn kàn pé ibi tí kò ti sí ìfọkàntán ni ìjíròrò náà ti wáyé, tó sì ní àwọn kò lè fẹnukò lẹ́ẹ̀kan náà lórí àwọn ìbéèrè kóówá àwón.

Kí ni Amẹ́ríkà sọ?

Ẹ̀wẹ̀, Amẹ́ríkà sọ pé àwọn nǹkan tí kò lágbára ni àwọn ń bèèrè lọ́wọ́ Iran, tí wọ́n sì mú ọgbọ́n dání.

Igbákejì Ààrẹ Amẹ́ríkà, JD Vance ní Trump rán òun láti ṣojú rẹ̀, tó sì ní kí òun ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn fẹnukò lórí àlááfíà.

Vance ní gbogbo nǹkan tí àwọn le ṣe ni àwọn ṣe ṣùgbọ́n tí àwọn kò rí ẹnu rẹ̀ fi gun ibìkan.

Ó ní òun àtàwọn ikọ̀ òun kò ríbi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Iran kò ní tẹ̀síwájú láti máa ṣe àdó olóró "nuclear weapon" tàbí láti wá nǹkan tí wọ́n fi le ṣe é kíákíá.

Ó sọ pé ohun tó jẹ Ààrẹ Amẹ́ríkà lógún jùlọ nìyẹn, tó sì fi àìdunnú rẹ̀ hàn pé wọn kò fénukò lórí rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Vance kò mẹ́nuba Strait of Hormuz, ọ̀nà ojú omi tí wọ́n ń gbé epo rọ̀bì gbà tí Amẹ́ríkà ń fẹ́ kí Iran ṣí, èyí tí ìgbàgbọ́ sì wà pé ó jẹ́ kókó ìdí tí ìjíròrò náà fi ń wáyé.

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè Pakistan sọ pé ó pọn dandan kí àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì dáwọ́ ogun dúró ná gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fẹnukò lé lórí tẹ́lẹ̀ títí ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n dá fi máa pé.

Kò ì tíì sí àrídájú bóyá ìjíròrò míì máa wáyé láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì tí ọ̀sẹ̀ méjì náà máa fi pé.