Iran ṣàlàyé ìdí abájọ tó fi ṣèkọlù sí ibùdó ológun Amẹrika

Ọkọ ijagun ''drone'' lori alagbalugbu omi

Oríṣun àwòrán, US Navy via Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọmogun Iran, IRGC, ti ṣalaye idi ti wọn fi ṣekọlu si ibudo ologun ofurufu Amẹrika to wa lẹkun Middle East.

Ajọ IRGC ni oun ṣekọlu si ibudo naa lẹyin ti Amẹrika yin ado oloro si ẹkun guusu Iran.

Ajọ naa ko darukọ ibi ti ibudo ọhun wa, ṣugbọn ibudo ologun ofurufu Amẹrika to wa ni Kuwait sọ pe awọn ti dena ado oloro tawọn ọta yin sibẹ.

Ileeṣẹ ọmogun Amẹrika naa sọ pe awọn ọmogun Kuwait dena ado oloro ti Iran yin si Kuwait, amọ, ileeṣẹ ọmogun Amẹrika ko sọ boya ibudo ologun ofurufu wọn ni wọn yin ado oloro ọhun si.

Iran yin ado oloro naa lẹyin ti Amẹrika ja nnkan ijagun Iran to wa ni Strait of Hormuz lulẹ.

Ija to tun ṣẹṣẹ bẹrẹ yii le ṣakoba fun ijiroro jogun o mi to n lọ lọwọ laarin Amẹrika ati Iran.

Igba keji ree ti Amẹrika yoo yin ado oloro si Iran laarin ọjọ mẹta, wọn ni awọn n fi n daabo bo ara awọn ni.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmogun Amẹrika sọ pe ikọlu ti Iran ṣe si Kuwait tako ijiroro jogun o mi to n lọ lọwọ.

Amẹrika fofin de ajọ Iran to n gbowo lọwọ awọn ọkọ oju omi agbepo to n gba oju ọna Strait of Hormuz kọja

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ijọba Iran to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Esmail Baqai, naa ti bẹnu ẹtẹ lu ikọlu Amẹrika si Iran.

Baqai sọ pe igbesẹ yii fi han pe Amẹrika naa ti tako ijiroro jogun o mi to n lọ lọwọ.

O ni iwa ọdaran gbaa ni Amẹrika hu pẹlu bi o ṣe ṣe ikọlu si Iran.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Amẹrika sọ pe awọn fi ikolu tawọn ṣe si ẹkun guusu Iran daabo bo ara awọn ni.

Ibudo ado oloro Iran atawọn ọkọ oju omi ijagun to fẹ ko ado oloro si Strait of Hormuz lori omi tawọn ọkọ oju omi agbepo fẹ gba kọja ni Amẹrika lawọn ṣe ikọlu si.

Wọn ni ọpọ ọkọ oju omi agbepo ni ko le kọja nibẹ tori ogun to n lọ laarin Amẹrika ati Iran.

Amẹrika tun fofin de ajọ Iran to n gbowo lọwọ awọn ọkọ oju omi agbepo to n gba oju ọna Strait of Hormuz kọja ni Iran.

Amẹrika sọ pe oun tun le fofin de ẹnikẹni to ba san iru owo bẹẹ fun Iran.

Ida kan ninu ida marun un epo rọbi ati afẹfẹ gaasi lagbaaye ni wọn maa n gbe gba ọna Strait of Hormuz ni Iran.

Akọwe eto iṣuna l'Amẹrika, Scott Bessent, sọ pe Iran n fipa gbowo lowọ awọn oniṣowo lagbaaye eyi to tumọ si pe gbogbo ọna ni wọn fi n wa owo.

Ajọ IRGC sọ lọjọ Iṣẹgun wi pe oun ti yin ado oloro si baalu ijagun Amẹrika to wọ oju ofurufu Iran.