Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Francis Duru jáde láyé lásìkò àìsàn ranpẹ

Oríṣun àwòrán, Francis Duru/Instagram
Agboole tiata ni orílẹ̀èdè Nàìjíríà tún ti wọ aṣọ Ọ̀fọ̀ míì pẹlu bí ikú ṣe mú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà miran lọ.
Onítọ̀hún ni Veteran Francis Duru, tíí ṣe àgbà ojẹ nínú ìṣẹ tíátà, ó sì jáde láyé lásìkò àìsàn ranpẹ.
Ẹnì ọdún mẹtadinlọgọta nii ṣe.
Atẹjade táwọn ẹbí rẹ fisita lójú òpó ayélujára Instagram rẹ ní àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì lo fidi ìṣẹ̀lẹ̀ náà mulẹ, níbi tí wọn ti ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ fún àtìlẹyìn wọn.
Àtẹ̀jádenáà ni"Àwa ẹbí Francis Duru fi tẹduntẹdunkéde ikú rẹ̀ lásìkò àìsàn ranpẹ.
A mọ riri àwọn àdúrà àti ìfẹ́ yín, kí Ọlọ́run kò tẹ sí afẹ́fẹ́ rere. Àmín "

Oríṣun àwòrán, Francis Duru/Instagram
Àìsàn wo lo ṣe Francis Duru to mu ẹmi rẹ lọ?
Bi a ko ba gbagbe, ìròyìn gbalẹ̀ kan lórí ayélujára láìpẹ́ yìí pé gbajúmọ̀ òṣèré tíátà náà ń se àìsàn kan, èyí tó lè mú ẹmi rẹ lọ.
Àmọ́ ṣe ni Duru fi ọwọ́ rọ ìròyìn náà sẹ́yìn pé ofege lásán-làsàn ni ìròyìn náà, kí àwọn olólùfẹ́ òun si kẹ̀yìn si.
Losu Kẹfà ọdún 2026 yìí si ni àwọn olólùfẹ́ òṣèré tíátà náà bẹ̀rẹ̀ si ni ko aya sókè pe nnkan ń ṣe ọkùnrin náà torí bo ṣe ru hangogo nínú àwòrán rẹ kan tí wọn pin sórí ayélujára.
Síbẹ̀ síbẹ̀, Francis Duru ni kí wọ́n lọ fi ọkàn balẹ̀ torí àwòrán náà jẹ agbelẹrọ lásán èyí tó wà láti ta epo si aṣọ ààlà òun ni.
Àmọ́ ó ṣe ní laanu pé lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tí àwòrán náà jáde síta, ikú pa ojú ilumooka òṣèré tíátà náà dé.

Oríṣun àwòrán, Francis Duru/Instagram
Àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì nípa igbe ayé Francis Duru, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà to jáde láyé
Ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù Keje ọdún 1969 ni wọn bi Francis Duru síle ayé si orílẹ̀èdè Cameroon.
Àmọ́ ọmọ bibi ìpínlẹ̀ Imo ni àwọn òbí rẹ jẹ ṣùgbọ́n orílẹ̀èdè Cameroon náà lo ti kàwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti gírámà.
Francis Duru pada wa silẹ Nàìjíríà láti lọ sile ẹkọ fásitì tilu Portharcourt, nipinlẹ Rivers.
O yàn imọ ẹkọ nipa ere tíátà láàyò, to si kẹkọ jáde lọ́dún 1996.
Ọdún 1989 si lo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà gan-an gan-an pẹlu ere itage kan tí wọn pé ní Missing Mark èyí tí Ndubuisi Oko dari rẹ.
Àmọ́ ọdún 1995 lo ti di gbajumọ lẹ́yìn tó kopa ninu sinima kan tí wọn pé ní Rattlesnake níbi tó ti ṣe Ahanna nínú sinimá naa.
Ere aláwàdà si ni ère tíátà náà èyí tí Amaka Igwe to ti di olóògbé gbé jáde.
Ọpọlọpọ àmì ẹyẹ àmì idalọla ni Duru gba nìdí sinimá sise ati ipa to ko si àgbéga ẹka ìṣẹ tíátà.
Bákan náà, wọ́n yan Duru gẹ́gẹ́ bíi aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ètò àlàáfíà láti mọ riri ipa to ni lórí àwọn ọdọ
Lọ́dún 2020, Francis Duru tún gbà àmì ẹyẹ gẹ́gẹ́ òṣèré tíátà lọkunrin to pegede jùlọ ni ẹka ere tíátà ni èdè Igbo torí ipa to ko nínú eré tíátà tí wọn pé ní Mboputa
Olóògbé Francis Duru ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 2003 pẹlu Adokiye, tí Ọba Oke si fi ọmọ mẹ́rin si aarin wọn àmọ́ ọkan ninu awọn ọmọ yì, Ifeanyi, jade láyé ni osu kẹjọ ọdún 2024.
A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ olóògbé Francis Duru si afẹ́fẹ́ rere.
Àwọn ẹbí rẹ yóò sì kéde ìsìnkú rẹ láìpẹ́.

























