Àkọsílẹ̀ DNA ṣàwárí àwọn ọmọ tí bàbá wọn ti sọnù fún ọ̀pọ̀ ọdún
Awọn ile ẹjọ kan nilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ si n lo awọn akọsilẹ DNA lati ṣawari awọn ọmọ kan ti wọn ti sọnu amọ ti awọn obi wọn jẹ ọmọ ilẹ Gẹẹsi.
Lara irufẹ ọmọ naa ni Cathy ti baba rẹ jẹ ọkan lara awọn ọmọ ogun ilẹ Gẹẹsi to lọ kẹkọọ ni Kenya lọpọ ọdun sẹyin.
Awọn ologun naa fun ọpọ obinrin loyun lasiko ẹkọ wọn ni Kenya, wọn si bi ọmọ ti iye wọn to ọgọrun un.
Wayi o, BBC Africa Eye ti ṣe iwadii bi wọn ṣe lo akọsilẹ DNA lati so awọn ọmọ ogun naa pọ mọ awọn ọmọ wọn.
Lara awọn ọmọ ti wọn ri baba wọn ni Cathy to ṣawari baba rẹ loju opo Facebook amọ ti ọkunrin naa kọ lati ba sọrọ, koda ọkunrin ọhun fofin de oju opo Cathy to jẹ ọmọ rẹ.
Nigba to n sọrọ, Phil, to jẹ baba Cathy sọ pe nnkan nira fun oun lasiko naa latari awọn ọrẹ oun ti oun ti padanu loju ogun, koda o ni oun ko nile lori.
Wo fidio oke yii fun ẹ.



