Báyìí ni ikọ̀ aláàbò Iru Ekùn ṣe ń mu àdínkù ba ìjínigbé àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ tó lé ní 80,000 - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Olori ajijangbara fun ominira ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeniyi Adeyemo, tọpọ awọn eeyan mọ si Igboho, ti sọ pe iwa ọdaran to n pagidina eto aabo ti dinku rẹpẹtẹ nilẹ Yoruba lasiko yii.
Sunday Igboho jẹ ko di mimọ pe, latigba toun ti da ileeṣẹ eleto aabo Iru Ẹkun silẹ, ni adinku ti de ba gbogbo oniruuru iwa ọdaran bii ijinigbe, igbesunmọmi ati ipaniyan nipakupa.
Igboho lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, ọsẹ yii, pẹlu afikun pe ipa rere ni ileeṣẹ eleto aabo naa ti ko ninu idagbasoke eto aabo nilẹ Naijiria, paapaa lẹkun Iwọ Oorun.
"Ijinigbe ti dinku nilẹ Yoruba, awọn ọlọpaa ati ileesẹ alaabo miran n fun wa ni igboya lati tẹpa mọ iṣẹ"
Atẹjade naa ni Igboho salaye pe ijinigbe kaakiri ẹkun Iwọ-Oorun orileede Naijiria ni iwa ijinigbe ti dinku.
O ni eyi ri bẹẹ lati ipasẹ iranlọwọ ileeṣẹ eto aabo ibilẹ to n ri iranlọwọ gba lati ọfọ awọn eleto aabo ijọba apapọ.
Igboho Ooṣa gẹgẹ bi wọn tun ṣe maa n pe e, jẹ ko di mimọ pe awọn ileeṣẹ eleto aabo bii ọlọpaa, ileeṣẹ ologun, ileeṣẹ eleto aabo, ileeṣẹ oludamọran pataki fun eto aabo, ati ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni wọn n fun awọn ni igboya lati tẹpa mọ iṣẹ.
"Olori ologun, Ọgagun Christopher Musa; Ọga ọlọpaa patapata, Tunji Disu, alakoso agba fun DSS, Adeola Oluwatosin Ajayi; oludamọran pataki loiri eto aabo, Nuhu Ribadu, ati gbogbo awọn ọga ọlọpaa lẹkun Iwọ-Oorun, Kwara ati Niger ni wọn ti gbaruku ti iṣẹ wa.
"Lai si atilẹyin wọn, o ṣee ṣe ka ma ri awọn aṣeyọri nla ti a ti ṣe yii ṣe,"Igboho fidi rẹ mulẹ.
Bakan naa lo gbe oriyin fun gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba lori atilẹyin ti wọn n fun iru Ẹkun, bẹẹ lo rọ gbogbo ọmọ Naijiria lai nii ṣe pẹlu ẹya tabi ẹsin kankan lati ri iṣẹ aabo gẹgẹ bi ajumọṣe.




























