"N25.5m, àpò ìrẹsì, epo pẹtiró àtàwọn nńkan míì ni ajínigbé gbà lọ́wọ́ wa, káwọn èèyàn wa ní Eda Oniyo tó gba ìtúsílẹ̀, Irọ́ ni, àwa ọlọ́pàá, ológun, Àmọ̀tẹ́kùn ló gbà wọ́n sílẹ̀"

Ọkọ bọọsi ti wọn fi ko awọn eeyan naa de, iya kan gbe ọmọde to ri ru pupo dani, awọn kan ṣi wa ninu ọkọ naa nigba ti ọlọpaa kan duro lẹnu ọna, ti obinrin kan si kọyin si i.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Loootọ ni pe awọn olujọsin ti awọn ajinigbe gbe lọ niluu Eda Oniyo niluu Ekiti loṣu meji sẹyin ti gba itusilẹ, ti wọn si ti n gba itọju nileewosan pẹlu, amọ ọfẹ kọ ni itusilẹ naa ba de.

Yatọ si owo ti iye rẹ to miliọnu mẹẹẹdọgbọn aabọ (N25.5m) ti awọn ajinigbe naa gba bii owo itusilẹ bi a ṣe gbọ, awọn nnkan jijẹ ati lilo ti ko lonka tun bọ lati ọwọ ara ilu Eda Oniyo, nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi Alaga ẹgbẹ to n ri si idagbasoke Eda Oniyo, (Eda Oniyo Development Union), Rufus Ajayi ṣe fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC, o ni awọn ajinigbe naa tun gba apo irẹsi pupọ titi to fi mọ epo bẹntiroolu atawọn nnkan mimu.

Awọn eeyan to ṣẹṣẹ gba itusilẹ kuro ni ahamọ ajinigbe

"Miliọnu mẹwaa aabọ ni awọn araalu kọkọ da pẹlu ọpọlọpọ apo irẹsi, amọ awọn ajinigbe naa ko tu awon eeyan wa silẹ''

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Alagba Ajayi sọ pe miliọnu mẹwaa aabọ naira ni awọn ara ilu ti kọkọ da pẹlu apo irẹsi, ọpọlọpọ ọti, epo bẹntiroolu ati oriṣiriṣi nnkan miiran ṣugbọn ti awọn ajinigbe naa kọ lati tu awọn eniyan awọn silẹ.

Ajayi ni lẹyin naa ni wọn da miliọnu mẹwaa mii ki awọn ajinigbe naa to tu awọn eeyan yii silẹ.

Alaga awọn ọmọ ẹgbẹ Eda-Oniyo naa kọminu lori iha ti ijọba ipinlẹ Ekiti kọ lori ọrọ ijinigbe naa bo ṣe fẹsun kan pe ijọba ko gbe awọn igbesẹ to yẹ lati gba itusilẹ awọn eeyan awọn.

Ṣaaju ni ọkan lara awọn ti wọn ji gbe naa, ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84) ti padanu ẹmi rẹ si igbekun awọn ajinigbe naa, ti wọn si gbe oku rẹ silẹ.

Awọn eeyan naa ti wa nile iwosan ijọba ipinlẹ Ekiti, EKSUTH fun iwosan ati itọju to peye.

"Owo ti a da laaarin ara wa niluu atawon eyi ti a ya lo gba awọn eeyan wa silẹ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi Ajayi ṣe wi:

" Idasi Ọlọrun ni awọn eeyan yii fi ri itusilẹ gba. Ọpọ igba la fi wa ninu inira. A gba aawẹ, a gbadura a tun da owo jọ lati gba awọn eeyan wa kuro nigbekun ni."

Miliọnu lọna ọgọrun-un kan naira (N100 million) lo ni awọn ajinigbe naa beere, ko too di pe awọn pada san miliọnu mẹẹẹdọgbọn aabọ naira.

Ajayi fi kun un pe owo tan lọwọ awon eeyan ilu to n dawo naa, koda awọn araalu Eda Oniyo to wa nilẹ okeere fi owo ranṣẹ.

Alagba Ajayi sọ pe awọn eeyan dawo naa debi pe ẹgbẹrun kan naira gan-an ko kere, o ni awọn ṣalaye fawọn ajinigbe naa pe awọn ko niru owo ti wọn n beere, amọ wọn ko dahun.

"Wọn taku pe awọn yoo gba miliọnu mẹẹẹdogun miran pẹlu ounjẹ atawọn nnkan mi-in."

Gẹgẹ bo ṣe wi:

Wọn gba apo irẹsi, nnkan mimu ọlọkan- o-jọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ lọwọ wa.

O fi kun alaye naa pe eeyan mẹta ninu awọn to n ba awọn ajinigbe naa sọrọ lo kuro niluu lati ọjọ mẹta ṣaaju idasilẹ awọn to wa nigbekun, wọn si rin irinajo lọ si aginju tawọn eeyan naa wa lati gbe awọn ohun ti wọn beere fun wọn.

Ajayi koro oju si ijọba ipinlẹ Ekiti lori ọwọ ti wọn fi mu iṣẹlẹ yii.

"Ijọba ko da wa lohun ba a ṣe ro pe wọn yoo ṣe, amọ ọrọ wọn ye mi, bijọba ba n sanwo fun ajinigbe taara, o le jẹ ki wọn maa ji eeyan gbe lọsọọsẹ.

"Nipari, owo ti a da laaarin ara wa atawọn ti a ya lo gba awọn eeyan wa silẹ."

Irọ ni, ọlọpaa, ologun, Amọtẹkun atawọn ẹṣọ aabo mii lo gba awọn eeyan naa silẹ- Sunday Abutu, Alukoro ọlọpaa Ekiti

Lodi si ohun ti Alagba Ajayi wi, kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ekiti sọ pe awọn agbofinro lo ṣiṣẹ itusilẹ naa.

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, SP Sunday Abutu fi sita lọjọ Satide lo ti ṣalaye pe ifọwọsowọpọ ikọ ọlọpaa, awọn ologun, Amotekun atawọn ẹṣọ aabo mi-in lo jẹ ki itusilẹ naa waye.

Apa kan atẹjade naa ka pe: " Bi a ṣe gba awọn eeyan naa silẹ waye pẹlu ajọṣe iṣẹ ikọ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa, ologun, Amotekun, awọn ọdẹ ibilẹ atawọn ẹṣọ mi-in.

"Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, CP Michael Falade, gboriyin fawọn ẹṣọ atawọn to ṣiṣẹ naa ti wọn fi gba awọn eeyan naa silẹ.

SP Abutu fi kun un pe iṣẹ ti n lọ lati mu awọn to wa nidii ijinigbe naa.

O rọ awọn araalu lati fi ọkan balẹ, nitori aabo to peye yoo wa fun ẹmi ati dukia wọn.

Gomina Oyebanji ṣabẹwo sawọn ti wọn gba itusilẹ naa nile iwosan

Gomina Biodun Oyebanji pẹlu awọn ti wọn jọ lọ sile iwosan naa ree lasiko abẹwo rẹ sawọn to gba itusilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook

Lati ki awọn to ṣẹṣẹ ti igbekun ajinigbe naa pẹlẹ, Gomina ipinlẹ Ekiti, Biodun Oyebanji, ṣabẹwo si wọn lojọ Aiku ana, nileewosan ti won ti n gba itọju.

Ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ti ipinlẹ Ekiti ti a mọ si Ekiti State University Teaching Hospital (EKSUTH), to wa l'Ado-Ekiti, ni awon eeyan naa ti n gba itoju bayii.

Ọjọ keji ti awọn eeyan naa de sileewosan ọhun ni Oyebanji bẹ wọn wo, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹ lu iha ti ijọba rẹ ko si iṣẹlẹ naa lati ibẹrẹ.

Awọn eeyan n sọ pe ko si aṣoju ijọba kankan to wa nibẹ nigba ti awọn eeyan naa de, bẹẹ lo ti rẹ wọn to bẹẹ to jẹ niṣe ni wọn n gbe wọn, pupọ wọn ko le fi ẹsẹ rin.

Ṣaa, nigba to n sọrọ nileewosan naa, Oyebanji,ti ọga agba lẹka eto ilera ipinlẹ Ekiti, Abilekọ Olusola Gbenga-Igotun, gba lalejo, koro oju si iṣẹlẹ yii.

Gomina sọ pe oun fi da awọn araalu loju pe igbesẹ akin loun n gbe lati ri I pe aabo wa fun ẹmi ati dukia wọn, oun yoo si ri I daju pe Ekiti ki I ṣe ibugbe awọn ajinigbe.

O kilọ fawọn araalu lati ma ṣe ki oṣelu bọ ọrọ aabo ati ijinigbe, Oyebanji sọ pe ọrọ aabo ki I ṣe nnkan yẹpẹrẹ.

Lẹyin naa lo ba awọn to ti igbekun de naa yọ, o ba wọn dupẹ pe wọn yọ ninu ewu. Oyebanji ṣapejuwe ohun ti won la kọja bii nnkan to nira pupọ.

O ni ijọba bi yoo san gbogbo owo itọju wọn, awọn yoo si tun pese iranwọ ti yoo mu wọn le ṣe daadaa laarin awọn eeyan pada.

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju: Ìṣọ́ òru di ibùdó ẹ̀jẹ̀ níjọ CAC Eda Oniyo l‘Ekiti, agbébọn pa pásítọ̀, jí ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ gbé lọ

Awọn agbebọn faṣọ boju, wọn gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Others

Tẹ o ba gbagbe, iṣọ oru ni wọn n ṣe lọwọ ninu ṣọọsi CAC Eda Oniyo-Ekiti lọjọ iṣẹlẹ naa, ti awọn agbebọn fi de ti wọn ti yinbọn pa pasitọ ti wọn si ji awọn ọmọ ijọ gbe lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti ni nnkan bii ago mẹwaa abọ alẹ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni awọn agbebọn marun un ṣadeede ya wọ ṣọọṣi naa.

Wọn ni isẹlẹ naa waye lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ, ti wọn si yinbọn pa alufaa ijọ naa.

Lẹyin ti wọn ṣekupa alufaa ijọ ọhun tan, ni wọn ji awọn ọmọ ijọ kan gbe lọ.

Bi eyi ṣe waye ni awọn ọlọpaa, awọn eṣọ Amotekun atawọn fijilante ti bẹ sinu igbo lati doola awọn ọmọ ijọ ti wọn jigbe lọ.

Kọmiṣọna ọlọpaa Ekiti rọ awọn olugbe ilu naa nigba naa pe ki wọn ma se foya tori awọn agbofinro yoo ṣagbara wọn lati doola awọn ti wọn ji gbe lọ.